ÌRÒYÌN Wọn yinbọn pa igbakeji MC Oluọmọ nibi ipolongo ibo APC l’Ekoo July 11, 2021 Tomiwhan Tomiwhan, Eko Niṣe lọrọ di bo-o-lọ-o-yago nigba ti iro ibọn ṣadeede dun, to si ṣeku pa igbakeji alaga ẹgbẹ onimọto NURTW, ẹka ti Eko, Ọgbẹni Kayọde Samuel, ti inagijẹ rẹ n jẹ Epo Kinkin, nibi eto kampeeni ẹgbẹ APC kan ti wọn ṣe lagbegbe Agboju, nijọba ibilẹ Onidagbasoke Oriade, l’Ekoo. Ba a ṣe gbọ, owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, niṣẹlẹ naa waye, ọkan lara awọn ero to pejọ sabẹ kanopi ti wọn ti n polongo ibo ni wọn lo yinbọn fun oloogbe naa. Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe ọkan lara awọn to fẹẹ dije fun ipo alaga kansu Oriade lagbegbe Agboju ni Epo kinkin n ṣatilẹyin fun lọwọ nibi ipolongo ọhun ti wọn fi yinbọn pa a. O ni niṣe lọrọ di pẹẹ-n-tuka gbara tawọn eeyan gburoo ibọn, ti oloogbe naa si kigbe oro laarin awọn ero to wa nita, nibi ti wọn ti yinbọn fun. O ni nigba tawọn fi maa mọ ohun to n ṣẹlẹ, Epo Kinkin ti ṣubu lulẹ sinu agbara ẹjẹ, o si ti ku. Lara awọn to wa nibi ipo...